Joẹli 1:3
Joel 1:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín, ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn, ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn.
Joel 1:3 in English
Joel 1:3 · Berean Standard Bible
Tell it to your children; let your children tell it to their children, and their children to the next generation.
Context
1Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Joẹli ọmọ Petueli wá. 2Ẹ gbọ́ èyí ẹ̀yin àgbàgbà;
ẹ fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ará ilẹ̀ náà.
Ǹjẹ́ irú èyí ha wà ní ọjọ́ yín,
tàbí ní ọjọ́ àwọn baba yín? 3Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín,
ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn,
ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn. 4Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kù
ní ọ̀wọ́ eṣú ńlá ńlá ti jẹ,
èyí tí ọ̀wọ́ eṣú ńlá ńlá jẹ kù
ní eṣú kéékèèké jẹ,
èyí tí eṣú kéékèèké jẹ kù
ni eṣú apanirun mìíràn jẹ. 5Ẹ jí gbogbo ẹ̀yin ọ̀mùtí kí ẹ sì sọkún
ẹ hu gbogbo ẹ̀yin ọ̀mu-wáìnì;
ẹ hu nítorí wáìnì tuntun
nítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.