Native Bible

Joel 1:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀; ẹ pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà, nítorí alikama àti nítorí ọkà barle; nítorí ìkórè oko ṣègbé.

Joel 1:11 in English

Joel 1:11 · Berean Standard Bible

Be dismayed, O farmers, wail, O vinedressers, over the wheat and barley, because the harvest of the field has perished.

Context

9A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímu kúrò ní ilé Olúwa. Àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa. 10Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a fi ọkà ṣòfò: ọtí wáìnì tuntun gbẹ, òróró ń bùṣe. 11Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀; ẹ pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà, nítorí alikama àti nítorí ọkà barle; nítorí ìkórè oko ṣègbé. 12Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù; igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú, àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ. Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn. 13Ẹ di ara yín ni àmùrè, sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà: ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi, nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.