Joẹli 1:10
Joel 1:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a fi ọkà ṣòfò: ọtí wáìnì tuntun gbẹ, òróró ń bùṣe.
Joel 1:10 in English
Joel 1:10 · Berean Standard Bible
The field is ruined; the land mourns. For the grain is destroyed, the new wine is dried up, and the oil fails.
Context
8Ẹ pohùnréré ẹkún bí wúńdíá
tí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ dí ni àmùrè, nítorí ọkọ ìgbà èwe rẹ̀. 9A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímu
kúrò ní ilé Olúwa.
Àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀,
àwọn ìránṣẹ́ Olúwa. 10Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀,
nítorí a fi ọkà ṣòfò:
ọtí wáìnì tuntun gbẹ, òróró ń bùṣe. 11Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀;
ẹ pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà,
nítorí alikama àti nítorí ọkà barle;
nítorí ìkórè oko ṣègbé. 12Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù;
igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú,
àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ.
Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.