Jobu 9:18
Job 9:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi, ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi.
Job 9:18 in English
Job 9:18 · Berean Standard Bible
He does not let me catch my breath, but overwhelms me with bitterness.
Context
16Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn,
èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi. 17Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá,
ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí. 18Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi,
ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi. 19Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó!
Alágbára ni, tàbí ní ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò? 20Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi yóò dá mi lẹ́bi;
bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.