Native Bible

Job 9:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn, èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi.

Job 9:16 in English

Job 9:16 · Berean Standard Bible

If I summoned Him and He answered me, I do not believe He would listen to my voice.

Context

14“Kí ní ṣe tí èmi ti n o fi ba ṣàròyé? Tí èmi yóò fi ma ṣe àwáwí? 15Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn; ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú. 16Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn, èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi. 17Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá, ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí. 18Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi, ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.