Native Bible

Job 7:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí mo wí pé, ibùsùn mi yóò tù mí lára, ìtẹ́ mi yóò mú ara mi fúyẹ́ pẹ̀lú.

Job 7:13 in English

Job 7:13 · Berean Standard Bible

When I think my bed will comfort me and my couch will ease my complaint,

Context

11“Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́, èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi, èmi yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi. 12Èmi a máa ṣe Òkun tàbí ẹ̀mí búburú, tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi? 13Nígbà tí mo wí pé, ibùsùn mi yóò tù mí lára, ìtẹ́ mi yóò mú ara mi fúyẹ́ pẹ̀lú. 14Nígbà náà ni ìwọ fi àlá da yọ mi lénu bò mi, ìwọ sì fi ìran òru dẹ́rùbà mí. 15Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti fún pa àti ikú ju kí ń wà láààyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.