Native Bible

Job 5:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú-ọmọ rẹ ó sì pọ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko igbó.

Job 5:25 in English

Job 5:25 · Berean Standard Bible

You will know that your offspring will be many, your descendants like the grass of the earth.

Context

23Nítorí pé ìwọ ti bá òkúta igbó mulẹ̀, àwọn ẹranko igbó yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà. 24Ìwọ ó sì mọ̀ pé àlàáfíà ni ibùjókòó rẹ wà, ìwọ yóò sì máa ṣe ìbẹ̀wò ibùjókòó rẹ, ìwọ kì yóò ṣìnà. 25Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú-ọmọ rẹ ó sì pọ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko igbó. 26Ìwọ yóò wọ isà òkú rẹ ní ògbólógbòó ọjọ́, bí síírí ọkà tí ó gbó tí á sì kó ní ìgbà ìkórè rẹ̀. 27“Kíyèsi i, àwa ti wádìí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ó rí! Gbà á gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ìre ara rẹ ni.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.