Native Bible

Job 5:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà, àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ.

Job 5:19 in English

Job 5:19 · Berean Standard Bible

He will rescue you from six calamities; no harm will touch you in seven.

Context

17“Kíyèsi i, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí, nítorí náà, má ṣe gan ìbáwí Olódùmarè. 18Nítorí pé òun a máa pa ni lára, síbẹ̀ òun a sì tún dì í ní ìdì ìtura, ó sá lọ́gbẹ́, a sì fi ọwọ́ rẹ̀ di ojú ọgbẹ̀ náà jiná. 19Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà, àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ. 20Nínú ìyanu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú àti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà. 21A ó pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ iná ahọ́n, bẹ́ẹ̀ ní ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìparun tí ó bá dé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.