Native Bible

Job 5:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Kíyèsi i, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí, nítorí náà, má ṣe gan ìbáwí Olódùmarè.

Job 5:17 in English

Job 5:17 · Berean Standard Bible

Blessed indeed is the man whom God corrects; so do not despise the discipline of the Almighty.*

Context

15Ṣùgbọ́n ó gba tálákà là ní ọwọ́ idà, lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára. 16Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún tálákà, àìṣòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́. 17“Kíyèsi i, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí, nítorí náà, má ṣe gan ìbáwí Olódùmarè. 18Nítorí pé òun a máa pa ni lára, síbẹ̀ òun a sì tún dì í ní ìdì ìtura, ó sá lọ́gbẹ́, a sì fi ọwọ́ rẹ̀ di ojú ọgbẹ̀ náà jiná. 19Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà, àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.