Native Bible

Job 5:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè ara wọn, àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tì ṣubú ní ògèdèǹgbé.

Job 5:13 in English

Job 5:13 · Berean Standard Bible

He catches the wise in their craftiness,* and sweeps away the plans of the cunning.

Context

11Láti gbé àwọn orílẹ̀-èdè lékè kí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu. 12Ó yí ìmọ̀ àwọn alárékérekè po, bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdáwọ́lé wọn ṣẹ. 13Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè ara wọn, àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tì ṣubú ní ògèdèǹgbé. 14Wọ́n sáré wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sán; wọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru ni. 15Ṣùgbọ́n ó gba tálákà là ní ọwọ́ idà, lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.