Jobu 41:9
Job 41:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kíyèsi, ìgbìyànjú láti mú un ní asán; ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì?
Job 41:9 in English
Job 41:9 · Berean Standard Bible
Surely hope of overcoming him is false. Is not the sight of him overwhelming?
Context
7Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin gun awọ rẹ̀,
tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ìpẹja. 8Fi ọwọ́ rẹ lé e lára,
ìwọ ó rántí ìjà náà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. 9Kíyèsi, ìgbìyànjú láti mú un ní asán;
ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì? 10Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè.
Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi. 11Ta ni ó kọ́kọ́ ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san án fún un?
Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.