Native Bible

Job 4:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

‘Ẹni kíkú le jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run, ènìyàn ha le mọ́ ju ẹlẹ́dàá rẹ̀ bí?

Job 4:17 in English

Job 4:17 · Berean Standard Bible

‘Can a mortal be more righteous than God, or a man more pure than his Maker?

Context

15Nígbà náà ni ẹ̀mí kan kọjá lọ ní iwájú mi, irun ara mi dìde dúró ṣánṣán. 16Ó dúró jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n èmi kò le wo àpẹẹrẹ ìrí rẹ̀, àwòrán kan hàn níwájú mi, ìdákẹ́rọ́rọ́ wà, mo sì gbóhùn kan wí pé, 17‘Ẹni kíkú le jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run, ènìyàn ha le mọ́ ju ẹlẹ́dàá rẹ̀ bí? 18Kíyèsi i, òun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, nínú àwọn angẹli rẹ̀ ní ó sì rí ẹ̀ṣẹ̀. 19Mélòó mélòó àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀, ẹni tí ìpìlẹ̀ wọ́n jásí erùpẹ̀ tí yóò di rírun kòkòrò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.