Native Bible

Job 39:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí? Tàbí ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru?

Job 39:9 in English

Job 39:9 · Berean Standard Bible

Will the wild ox consent to serve you? Will he stay by your manger at night?

Context

7Ó rẹ́rìn-ín sí ariwo ìlú, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbọ́ igbe darandaran. 8Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjẹ oko rẹ̀, òun a sì máa wá ewé tútù gbogbo rí. 9“Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí? Tàbí ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru? 10Ìwọ le fi òkun tata de àgbáǹréré nínú aporo? Tàbí ó jẹ́ máa fa ìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn? 11Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀lé e nítorí agbára rẹ̀ pọ̀? Ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.