Native Bible

Job 38:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí? Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọrọ kìnnìún lọ́rùn,

Job 38:39 in English

Job 38:39 · Berean Standard Bible

Can you hunt the prey for a lioness or satisfy the hunger of young lions

Context

37Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmọ̀? Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde, 38nígbà tí erùpẹ̀ di líle, àti ògúlùtu dìpọ̀? 39“Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí? Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọrọ kìnnìún lọ́rùn, 40nígbà tí wọ́n bá mọ́lẹ̀ nínú ihò tí wọ́n sì ba ní ibùba de ohun ọdẹ? 41Ta ni ó ń pèsè ohun jíjẹ fún ẹyẹ ìwò, nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ń ké pe Ọlọ́run, tí wọ́n sì máa ń fò kiri nítorí àìní ohun jíjẹ?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.