Native Bible

Job 38:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí, nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dá mi lóhùn.

Job 38:3 in English

Job 38:3 · Berean Standard Bible

Now brace yourself * like a man; I will question you, and you shall inform Me.*

Context

1Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé, 2“Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìlóye láti fi ṣókùnkùn bo ìmọ̀ mi? 3Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí, nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dá mi lóhùn. 4“Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye. 5Ta ni ó fi ìwọ̀n rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n? Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.