Native Bible

Job 36:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì gàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye.

Job 36:5 in English

Job 36:5 · Berean Standard Bible

Indeed, God is mighty, but He despises no one; He is mighty in strength of understanding.

Context

3Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jíjìn wá, èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi. 4Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké nítòótọ́; ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. 5“Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì gàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye. 6Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí, ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà. 7Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo, ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́; àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.