Jobu 36:28
Job 36:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀ ìrì rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì fi ń sẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ lórí ènìyàn.
Job 36:28 in English
Job 36:28 · Berean Standard Bible
which the clouds pour out and shower abundantly on mankind.
Context
26Kíyèsi i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó,
bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí. 27“Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi òjò sílẹ̀,
kí wọn kí ó kán bí òjò ní ìkùùkuu rẹ̀, 28tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀ ìrì rẹ̀ sílẹ̀,
tí ó sì fi ń sẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ lórí ènìyàn. 29Pẹ̀lúpẹ̀lú ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè ní ìmọ̀ ìtànká àwọsánmọ̀,
tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀? 30Kíyèsi i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ ká
ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.