Native Bible

Job 35:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dáhùn nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.

Job 35:12 in English

Job 35:12 · Berean Standard Bible

There they cry out, but He does not answer, because of the pride of evil men.

Context

10Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé, ‘Níbo ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru; 11tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọn ẹranko ayé lọ, tí ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’ 12Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dáhùn nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú. 13Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ asán; bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí. 14Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì í rí i, ọ̀rọ̀ ìdájọ́ ń bẹ níwájú rẹ, ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.