Jobu 31:10
Job 31:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn, kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.
Job 31:10 in English
Job 31:10 · Berean Standard Bible
then may my own wife grind grain for another, and may other men sleep with her.
Context
8ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ,
àní kí a fa irú-ọmọ mi tu. 9“Bí àyà mi bá di fífà sí ipasẹ̀ obìnrin kan,
tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu-ọ̀nà ilé aládùúgbò mi, 10kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn,
kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀. 11Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àní,
ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀. 12Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun,
tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.