Native Bible

Job 30:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú oòrùn; èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́.

Job 30:28 in English

Job 30:28 · Berean Standard Bible

I go about blackened, but not by the sun. I stand up in the assembly and cry for help.

Context

26Nígbà tí mo fojú ṣọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé; nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé. 27Ikùn mí n ru kò sì sinmi, ọjọ́ ìpọ́njú ti dé bá mi. 28Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú oòrùn; èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́. 29Èmi ti di arákùnrin ìkookò, èmi di ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò. 30Àwọ̀ mi di dúdú ní ara mi; egungun mi sì jórun fún ooru.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.