Jobu 30:23
Job 30:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi sá à mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọ sínú ikú, sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè.
Job 30:23 in English
Job 30:23 · Berean Standard Bible
Yes, I know that You will bring me down to death, to the place appointed for all the living.
Context
21Ìwọ padà di ẹni ìkà sí mi;
ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ fi dè mí ní ọ̀nà. 22Ìwọ gbé mi sókè sí inú ẹ̀fúùfù, ìwọ mú mi fò lọ,
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì sọ mí di asán pátápátá. 23Èmi sá à mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọ sínú ikú,
sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè. 24“Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóò ha nawọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubú rẹ̀,
tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀. 25Èmi kò ha sọkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro?
Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún tálákà bí?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.