Native Bible

Job 30:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú; wọ́n sì sọ ìparun mi di púpọ̀, àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.

Job 30:13 in English

Job 30:13 · Berean Standard Bible

They tear up my path; they profit from my destruction, with no one to restrain them.*

Context

11Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú; àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìdẹ̀kùn níwájú mi. 12Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi; wọ́n tì ẹsẹ̀ mi kúrò, wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dè mí. 13Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú; wọ́n sì sọ ìparun mi di púpọ̀, àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. 14Wọ́n ya sí mi bí i omi tí ó ya gbuuru; ní ariwo ńlá ni wọ́n rọ́ wá. 15Ẹ̀rù ńlá bà mí; wọ́n lépa ọkàn mi bí ẹ̀fúùfù, àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.