Jobu 30:10
Job 30:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnà sí mi, wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sí mi lójú.
Job 30:10 in English
Job 30:10 · Berean Standard Bible
They abhor me and keep far from me; they do not hesitate to spit in my face.
Context
8Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé,
àní àwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀. 9“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin;
àní èmi di ẹni ìṣọ̀rọ̀ sí láàrín wọn. 10Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnà sí mi,
wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sí mi lójú. 11Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú;
àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìdẹ̀kùn níwájú mi. 12Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi;
wọ́n tì ẹsẹ̀ mi kúrò,
wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dè mí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.