Native Bible

Job 3:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti èwe àti àgbà wà níbẹ̀, ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀.

Job 3:19 in English

Job 3:19 · Berean Standard Bible

Both small and great are there, and the slave is freed from his master.

Context

17Níbẹ̀ ni ẹni búburú ṣíwọ́ ìyọnilẹ́nu, níbẹ̀ ni ẹni àárẹ̀ wà nínú ìsinmi. 18Níbẹ̀ ni àwọn ìgbèkùn sinmi pọ̀, wọn kò gbóhùn amúnisìn mọ́. 19Àti èwe àti àgbà wà níbẹ̀, ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀. 20“Nítorí kí ni a ṣe fi ìmọ́lẹ̀ fún òtòṣì, àti ìyè fún ọlọ́kàn kíkorò, 21tí wọ́n dúró de ikú, ṣùgbọ́n òun kò wá, tí wọ́n wá a jù ìṣúra tí a bò mọ́lẹ̀ pamọ́ lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.