Native Bible

Job 29:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí, àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já.

Job 29:3 in English

Job 29:3 · Berean Standard Bible

when His lamp shone above my head, and by His light I walked through the darkness,

Context

1Pẹ̀lúpẹ̀lú, Jobu sì tún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, 2“Háà! ìbá ṣe pé èmi wà bí ìgbà oṣù tí ó kọjá, bí ọjọ́ tí Ọlọ́run pa mí mọ́, 3nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí, àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já. 4Bí mo ti rí nígbà ọ̀dọ́ mi, nígbà tí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi, 5nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi, nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká;

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.