Native Bible

Job 24:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ìhòhò ni wọn máa sùn láìní aṣọ, tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù.

Job 24:7 in English

Job 24:7 · Berean Standard Bible

Without clothing, they spend the night naked; they have no covering against the cold.

Context

5Kíyèsi i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó nínú ijù ni àwọn tálákà jáde lọ sí iṣẹ́ wọn, wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ; ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn. 6Olúkúlùkù a sì sá ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko, wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú. 7Ní ìhòhò ni wọn máa sùn láìní aṣọ, tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù. 8Ọ̀wààrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n, wọ́n sì lẹ̀ mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò. 9Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú, wọ́n sì gbà ọmọ tálákà nítorí gbèsè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.