Jobu 24:6
Job 24:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúkúlùkù a sì sá ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko, wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú.
Job 24:6 in English
Job 24:6 · Berean Standard Bible
They gather fodder in the fields and glean the vineyards of the wicked.
Context
4Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà,
àwọn tálákà ayé a fi agbára sá pamọ́. 5Kíyèsi i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó nínú ijù ni àwọn tálákà jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,
wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ;
ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn. 6Olúkúlùkù a sì sá ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko,
wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú. 7Ní ìhòhò ni wọn máa sùn láìní aṣọ,
tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù. 8Ọ̀wààrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n,
wọ́n sì lẹ̀ mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.