Jobu 24:3
Job 24:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n á sì da kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba lọ, wọ́n a sì gba ọ̀dá màlúù opó ní ohun ògo.
Job 24:3 in English
Job 24:3 · Berean Standard Bible
They drive away the donkey of the fatherless and take the widow’s ox in pledge.
Context
1“Ṣe bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmarè fún ìdájọ́?
Èéṣe tí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀? 2Wọ́n a sún àmì ààlà ilẹ̀,
wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n a sì bọ́ wọn. 3Wọ́n á sì da kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba lọ,
wọ́n a sì gba ọ̀dá màlúù opó ní ohun ògo. 4Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà,
àwọn tálákà ayé a fi agbára sá pamọ́. 5Kíyèsi i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó nínú ijù ni àwọn tálákà jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,
wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ;
ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.