Native Bible

Job 22:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lóòtítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmarè, ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Job 22:26 in English

Job 22:26 · Berean Standard Bible

Surely then you will delight in the Almighty and lift up your face to God.

Context

24tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀, lórí erùpẹ̀ àti wúrà Ofiri lábẹ́ òkúta odò, 25nígbà náà ní Olódùmarè yóò jẹ́ wúrà rẹ, àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. 26Lóòtítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmarè, ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run. 27Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò sì gbọ́ tìrẹ, ìwọ ó sì san ẹ̀jẹ́ rẹ. 28Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú, yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ; ìmọ́lẹ̀ yóò sì mọ́ sípa ọ̀nà rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.