Jobu 22:21
Job 22:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà; nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.
Job 22:21 in English
Job 22:21 · Berean Standard Bible
Reconcile now and be at peace with Him; thereby good will come to you.
Context
19Àwọn olódodo rí ìparun wọn, wọ́n sì yọ̀,
àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀ sì fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà pé, 20‘Lóòtítọ́ àwọn ọ̀tá wa ni a ké kúrò,
iná yóò sì jó oró wọn run.’ 21“Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà;
nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ. 22Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá,
kí o sì to ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ. 23Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró.
Bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.