Native Bible

Job 20:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i, àní a ó lé e lọ bi ìran òru.

Job 20:8 in English

Job 20:8 · Berean Standard Bible

He will fly away like a dream, never to be found; he will be chased away like a vision in the night.

Context

6Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run, ti orí rẹ̀ sì kan àwọsánmọ̀; 7ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀; àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’ 8Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i, àní a ó lé e lọ bi ìran òru. 9Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́. 10Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojúrere lọ́dọ̀ tálákà, ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.