Jobu 19:7
Job 19:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Kíyèsi, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára!’ Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi; mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́.
Job 19:7 in English
Job 19:7 · Berean Standard Bible
Though I cry out, ‘Violence!’ I get no response; though I call for help, there is no justice.
Context
5Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́,
tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú, 6kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú,
ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká. 7“Kíyèsi, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára!’ Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi;
mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́. 8Ó ṣọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá,
Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi. 9Ó ti bọ́ ògo mi,
ó sì ṣí adé kúrò ní orí mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.