Jobu 19:17
Job 19:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀mí mi ṣú àyà mi, àti òórùn mi ṣú àwọn ọmọ inú ìyá mi.
Job 19:17 in English
Job 19:17 · Berean Standard Bible
My breath is repulsive to my wife, and I am loathsome to my own family.
Context
15Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì;
èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn. 16Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn;
mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́. 17Ẹ̀mí mi ṣú àyà mi, àti òórùn mi
ṣú àwọn ọmọ inú ìyá mi. 18Àní àwọn ọmọdékùnrin fi mí ṣẹ̀sín,
mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi. 19Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi,
àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.