Native Bible

Job 19:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì; èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn.

Job 19:15 in English

Job 19:15 · Berean Standard Bible

My guests and maidservants count me as a stranger; I am a foreigner in their sight.

Context

13“Ó mú àwọn arákùnrin mi jìnà sí mi réré, àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátápátá. 14Àwọn alájọbí mi fàsẹ́yìn, àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi sì di onígbàgbé mi. 15Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì; èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn. 16Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn; mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́. 17Ẹ̀mí mi ṣú àyà mi, àti òórùn mi ṣú àwọn ọmọ inú ìyá mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.