Native Bible

Job 18:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí kí ni a ṣe ń kà wá sí bí ẹranko, tí a sì ń kà wá si bí ẹni ẹ̀gàn ní ojú yín?

Job 18:3 in English

Job 18:3 · Berean Standard Bible

Why are we regarded as cattle, as stupid in your sight?

Context

1Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn, ó sì wí pé, 2“Nígbà wo ni ẹ̀yin yóò tó fi ìdí ọ̀rọ̀ tì; ẹ rò ó, nígbẹ̀yìn rẹ̀ ni àwa ó tó máa sọ. 3Nítorí kí ni a ṣe ń kà wá sí bí ẹranko, tí a sì ń kà wá si bí ẹni ẹ̀gàn ní ojú yín? 4Ìwọ fa ara rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú ìbínú rẹ̀; kí a ha kọ ayé sílẹ̀ nítorí rẹ̀ bi? Tàbí kí a sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀? 5“Nítòótọ́ ìmọ́lẹ̀ ènìyàn búburú ni a ó pa kúrò, ọ̀wọ́-iná rẹ̀ kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.