Native Bible

Job 15:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípé ọjọ́ rẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù.

Job 15:32 in English

Job 15:32 · Berean Standard Bible

It will be paid in full before his time, and his branch will not flourish.

Context

30Òun kì yóò jáde kúrò nínú òkùnkùn; ọ̀wọ́-iná ni yóò jó ẹ̀ka rẹ̀, àti nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu Ọlọ́run ní a ó gba kúrò. 31Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀lé asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ. Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀. 32A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípé ọjọ́ rẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù. 33Yóò dàbí àjàrà tí a gbọn èso àìpọ́n rẹ̀ dànù, yóò sì rẹ̀ ìtànná rẹ̀ dànù bí i ti igi Olifi. 34Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebè yóò túká, iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.