Jobu 15:10
Job 15:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn arúgbó àti ògbólógbòó ènìyàn wà pẹ̀lú wa, tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ.
Job 15:10 in English
Job 15:10 · Berean Standard Bible
Both the gray-haired and the aged are on our side— men much older than your father.
Context
8Ìwọ gbúròó àṣírí Ọlọ́run rí?
Tàbí ìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ? 9Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀?
Òye kí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa? 10Àwọn arúgbó àti ògbólógbòó ènìyàn wà pẹ̀lú wa,
tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ. 11Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ?
Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ? 12Èéṣe ti ọkàn rẹ fi ń ti ọ kiri,
kí ni ìwọ tẹjúmọ́ tóbẹ́ẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.