Native Bible

John 9:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà àwọn Júù kò gbàgbọ́ nípa rẹ̀ pé ojú rẹ̀ ti fọ́ rí, àti pé ó sì tún ríran, títí wọ́n fi pe àwọn òbí ẹni tí a ti là lójú.

John 9:18 in English

John 9:18 · Berean Standard Bible

The Jews still did not believe that the man had been blind and had received his sight until they summoned his parents

Context

16Nítorí náà àwọn kan nínú àwọn Farisi wí pé, “Ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, nítorí tí kò pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.” Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Ọkùnrin tí í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò ha ti ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ àmì wọ̀nyí?” Ìyapa sì wà láàrín wọn. 17Nítorí náà, wọ́n sì tún wí fún afọ́jú náà pé, “Kí ni ìwọ ní wí nípa rẹ̀, nítorí tí ó là ọ́ lójú?” Ó sì wí pé, “Wòlíì ní í ṣe.” 18Nítorí náà àwọn Júù kò gbàgbọ́ nípa rẹ̀ pé ojú rẹ̀ ti fọ́ rí, àti pé ó sì tún ríran, títí wọ́n fi pe àwọn òbí ẹni tí a ti là lójú. 19Wọ́n sì bi wọ́n léèrè wí pé, “Ǹjẹ́ èyí ni ọmọ yín, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, a bí ní afọ́jú? Báwo ni ó ṣe ríran nísinsin yìí?” 20Àwọn òbí rẹ̀ dá wọn lóhùn wí pé, “Àwa mọ̀ pé ọmọ wa ni èyí, àti pé a bí i ní afọ́jú,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.