Johanu 9:17
John 9:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, wọ́n sì tún wí fún afọ́jú náà pé, “Kí ni ìwọ ní wí nípa rẹ̀, nítorí tí ó là ọ́ lójú?” Ó sì wí pé, “Wòlíì ní í ṣe.”
John 9:17 in English
John 9:17 · Berean Standard Bible
So once again they asked the man who had been blind, “What do you say about Him, since it was your eyes He opened?” “He is a prophet,” the man replied.
Context
15Nítorí náà àwọn Farisi pẹ̀lú tún bi í léèrè, bí ó ti ṣe ríran. Ọkùnrin náà fèsì, “Ó fi amọ̀ lé ojú mi, mo sì wẹ̀, báyìí mo sì ríran.” 16Nítorí náà àwọn kan nínú àwọn Farisi wí pé, “Ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, nítorí tí kò pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.”
Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Ọkùnrin tí í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò ha ti ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ àmì wọ̀nyí?” Ìyapa sì wà láàrín wọn. 17Nítorí náà, wọ́n sì tún wí fún afọ́jú náà pé, “Kí ni ìwọ ní wí nípa rẹ̀, nítorí tí ó là ọ́ lójú?”
Ó sì wí pé, “Wòlíì ní í ṣe.” 18Nítorí náà àwọn Júù kò gbàgbọ́ nípa rẹ̀ pé ojú rẹ̀ ti fọ́ rí, àti pé ó sì tún ríran, títí wọ́n fi pe àwọn òbí ẹni tí a ti là lójú. 19Wọ́n sì bi wọ́n léèrè wí pé, “Ǹjẹ́ èyí ni ọmọ yín, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, a bí ní afọ́jú? Báwo ni ó ṣe ríran nísinsin yìí?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.