Johanu 9:16
John 9:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà àwọn kan nínú àwọn Farisi wí pé, “Ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, nítorí tí kò pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.” Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Ọkùnrin tí í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò ha ti ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ àmì wọ̀nyí?” Ìyapa sì wà láàrín wọn.
John 9:16 in English
John 9:16 · Berean Standard Bible
Because of this, some of the Pharisees said, “This man is not from God, for He does not keep the Sabbath.” But others said, “How can a sinful man perform such signs?” And there was division among them.
Context
14Ọjọ́ ìsinmi ni ọjọ́ náà nígbà tí Jesu ṣe amọ̀, tí ó sì là á lójú. 15Nítorí náà àwọn Farisi pẹ̀lú tún bi í léèrè, bí ó ti ṣe ríran. Ọkùnrin náà fèsì, “Ó fi amọ̀ lé ojú mi, mo sì wẹ̀, báyìí mo sì ríran.” 16Nítorí náà àwọn kan nínú àwọn Farisi wí pé, “Ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, nítorí tí kò pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.”
Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Ọkùnrin tí í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò ha ti ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ àmì wọ̀nyí?” Ìyapa sì wà láàrín wọn. 17Nítorí náà, wọ́n sì tún wí fún afọ́jú náà pé, “Kí ni ìwọ ní wí nípa rẹ̀, nítorí tí ó là ọ́ lójú?”
Ó sì wí pé, “Wòlíì ní í ṣe.” 18Nítorí náà àwọn Júù kò gbàgbọ́ nípa rẹ̀ pé ojú rẹ̀ ti fọ́ rí, àti pé ó sì tún ríran, títí wọ́n fi pe àwọn òbí ẹni tí a ti là lójú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.