Johanu 8:43
John 8:43 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.
John 8:43 in English
John 8:43 · Berean Standard Bible
Why do you not understand what I am saying? It is because you are unable to accept My message.
Context
41Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.”
Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “a kò bí wa nípa panṣágà, a ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.” 42Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi, nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi. 43Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. 44Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké. 45Ṣùgbọ́n nítorí tí èmi ń sọ òtítọ́ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.