Johanu 8:41
John 8:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.” Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “a kò bí wa nípa panṣágà, a ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.”
John 8:41 in English
John 8:41 · Berean Standard Bible
You are doing the works of your father.” “We are not illegitimate children,” they declared. “Our only Father is God Himself.”
Context
39Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, “Abrahamu ni baba wa!”
Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Abrahamu. 40Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó sọ òtítọ́ fún yín, èyí tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, Abrahamu kò ṣe èyí. 41Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.”
Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “a kò bí wa nípa panṣágà, a ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.” 42Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi, nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi. 43Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.