Native Bible

John 8:40 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó sọ òtítọ́ fún yín, èyí tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, Abrahamu kò ṣe èyí.

John 8:40 in English

John 8:40 · Berean Standard Bible

But now you are trying to kill Me, a man who has told you the truth that I heard from God. Abraham never did such a thing.

Context

38Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba ni mo sọ, ẹ̀yin pẹ̀lú sì ń ṣe èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ baba yín.” 39Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, “Abrahamu ni baba wa!” Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Abrahamu. 40Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó sọ òtítọ́ fún yín, èyí tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, Abrahamu kò ṣe èyí. 41Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.” Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “a kò bí wa nípa panṣágà, a ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.” 42Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi, nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.