Johanu 8:16
John 8:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni, nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi.
John 8:16 in English
John 8:16 · Berean Standard Bible
But even if I do judge, My judgment is true, because I am not alone; I am with the Father who sent Me.*
Context
14Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo tilẹ̀ ń jẹ́rìí fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi: nítorí tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ń lọ; ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò lè mọ ibi tí mo ti wá, àti ibi tí mo ń lọ. 15Ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ nípa ti ara; èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni. 16Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni, nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi. 17A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì. 18Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rìí mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.