Native Bible

John 8:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.” Jesu wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi, máa lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”

John 8:11 in English

John 8:11 · Berean Standard Bible

“No one, Lord,” she answered. “Then neither do I condemn you,” Jesus declared. “Now go and sin no more.”

Context

9Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jesu nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàrín, níbi tí ó wà. 10Jesu sì dìde, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn olùfisùn rẹ dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?” 11Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.” Jesu wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi, máa lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́.” 12Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.” 13Nítorí náà àwọn Farisi wí fún un pé, “Ìwọ ń jẹ́rìí ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òtítọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.