Johanu 8:9
John 8:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jesu nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàrín, níbi tí ó wà.
John 8:9 in English
John 8:9 · Berean Standard Bible
When they heard this,* they began to go away one by one, beginning with the older ones, until only Jesus was left, with the woman standing there.
Context
7Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ́, ó gbe orí rẹ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.” 8Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀. 9Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jesu nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàrín, níbi tí ó wà. 10Jesu sì dìde, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn olùfisùn rẹ dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?” 11Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.”
Jesu wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi, máa lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.