Native Bible

John 8:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

John 8:12 in English

John 8:12 · Berean Standard Bible

Once again, Jesus spoke to the people and said, “I am the light of the world. Whoever follows Me will never walk in the darkness, but will have the light of life.”

Context

10Jesu sì dìde, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn olùfisùn rẹ dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?” 11Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.” Jesu wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi, máa lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́.” 12Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.” 13Nítorí náà àwọn Farisi wí fún un pé, “Ìwọ ń jẹ́rìí ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òtítọ́.” 14Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo tilẹ̀ ń jẹ́rìí fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi: nítorí tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ń lọ; ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò lè mọ ibi tí mo ti wá, àti ibi tí mo ń lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.