Native Bible

John 6:61 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn sí ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Èyí jẹ́ ìkọ̀sẹ̀ fún yín bí?

John 6:61 in English

John 6:61 · Berean Standard Bible

Aware that His disciples were grumbling about this teaching, Jesus asked them, “Does this offend you?

Context

59Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ nínú Sinagọgu, bí ó ti ń kọ́ni ní Kapernaumu. 60Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Ọ̀rọ̀ tí ó le ni èyí; ta ní lè gbọ́ ọ?” 61Nígbà tí Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn sí ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Èyí jẹ́ ìkọ̀sẹ̀ fún yín bí? 62Ǹjẹ́, bí ẹ̀yin bá sì rí i tí Ọmọ Ènìyàn ń gòkè lọ sí ibi tí ó gbé ti wà rí ń kọ́? 63Ẹ̀mí ní ń sọ ni di ààyè; ara kò ní èrè kan; ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo sọ fún yín, ẹ̀mí ni, ìyè sì ni pẹ̀lú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.