Native Bible

John 6:63 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀mí ní ń sọ ni di ààyè; ara kò ní èrè kan; ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo sọ fún yín, ẹ̀mí ni, ìyè sì ni pẹ̀lú.

John 6:63 in English

John 6:63 · Berean Standard Bible

The Spirit gives life; the flesh profits nothing. The words I have spoken to you are spirit and they are life.

Context

61Nígbà tí Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn sí ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Èyí jẹ́ ìkọ̀sẹ̀ fún yín bí? 62Ǹjẹ́, bí ẹ̀yin bá sì rí i tí Ọmọ Ènìyàn ń gòkè lọ sí ibi tí ó gbé ti wà rí ń kọ́? 63Ẹ̀mí ní ń sọ ni di ààyè; ara kò ní èrè kan; ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo sọ fún yín, ẹ̀mí ni, ìyè sì ni pẹ̀lú. 64Ṣùgbọ́n àwọn kan wà nínú yín tí kò gbàgbọ́.” Nítorí Jesu mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá ẹni tí wọ́n jẹ́ tí kò gbàgbọ́, àti ẹni tí yóò fi òun hàn. 65Ó sì wí pé, “Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, kò sí ẹni tí ó lè tọ̀ mí wá, bí kò ṣe pé a fi fún un láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.