Native Bible

John 6:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu sì gun orí òkè lọ, níbẹ̀ ni ó sì gbé jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

John 6:3 in English

John 6:3 · Berean Standard Bible

Then Jesus went up on the mountain and sat down with His disciples.

Context

1Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu kọjá sí apá kejì Òkun Galili, tí í ṣe Òkun Tiberia. 2Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ àmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn. 3Jesu sì gun orí òkè lọ, níbẹ̀ ni ó sì gbé jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 4Àjọ ìrékọjá ọdún àwọn Júù sì súnmọ́ etílé. 5Ǹjẹ́ bí Jesu ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Filipi pé, “Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.